4
Ìnilára, làálàá, àti àìlọ́rẹ̀ẹ́
Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn,
mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni,
wọn kò sì ní olùtùnú kankan,
agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára,
wọn kò sì ní olùtùnú kankan.
Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú
tí wọ́n sì ti lọ,
ó sàn fún wọn ju àwọn
tí wọ́n sì wà láààyè lọ.
Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju
àwọn méjèèjì lọ:
ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú
tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.
Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò
ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà,
àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn.
Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà;
kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí.
Kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo,
síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn.
Bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá,
àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?”
Eléyìí náà asán ni,
iṣẹ́ òsì!
 
Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan,
nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn.
10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀,
ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè,
ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú
tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!
11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru.
Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan,
àwọn méjì le è gbìjà ara wọn,
ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.
Asán ni ipò gíga
13 Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn. 14 Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀. 15 Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí. 16 Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.