Ìwé Wòlíì Mika
1
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.
2 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,
fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
kí Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín,
Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.
Ìdájọ́ tí o lòdì sí Samaria àti Jerusalẹmu
3 Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;
yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.
4 Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,
àwọn àfonífojì yóò sì pínyà,
bí idà níwájú iná,
bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
5 Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí,
àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli.
Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu?
Ǹjẹ́ Samaria ha kọ?
Kí ni àwọn ibi gíga Juda?
Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?
6 “Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá,
bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà.
Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.
Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.
7 Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́
gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun,
Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.
Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,
gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”
Ẹkún òun ọfọ̀
8 Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún,
èmi yóò sì pohùnréré ẹkún:
èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò.
Èmi yóò ké bí akátá,
èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.
9 Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán;
ó sì ti wá sí Juda.
Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi,
àní sí Jerusalẹmu.
10 Ẹ má ṣe sọ ní Gati
ẹ má ṣe sọkún rárá.
Ní ilẹ̀ Beti-Ofra
mo yí ara mi nínú eruku.
11 Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú,
ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri.
Àwọn tí ó ń gbé ni Saanani
kì yóò sì jáde wá.
Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀;
a ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.
12 Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre,
ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu.
13 Ìwọ olùgbé Lakiṣi,
dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára.
Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀
sí àwọn ọmọbìnrin Sioni,
nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.
14 Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀
fún Moreṣeti Gati.
Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli.
15 Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa.
Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli
yóò sì wá sí Adullamu.
16 Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀
nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára,
sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún,
nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.