18
Ènìyàn tí kò ba ni rẹ́ a máa lépa ìmọ̀ ara rẹ̀;
ó kọjú ìjà sí gbogbo ìdájọ́ òdodo.
 
Aláìgbọ́n kò rí inú dídùn sí òye
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí sísọ èrò tirẹ̀.
 
Nígbà ti ènìyàn búburú dé ni ẹ̀gàn dé,
nígbà ti ẹ̀gàn dé ni ìtìjú dé.
 
Ọ̀rọ̀ ẹnu ènìyàn jẹ́ omi jíjìn,
ṣùgbọ́n orísun ọgbọ́n jẹ́ odò tí ń sàn.
 
Kò dára kí ènìyàn ṣe ojúsàájú fún ènìyàn búburú
tàbí kí a fi ìdájọ́ òdodo du aláìṣẹ̀.
 
Ètè aláìgbọ́n dá ìjà sílẹ̀
ẹnu rẹ̀ sì ń ṣokùnfà ẹgba.
 
Ẹnu aláìgbọ́n ni ó ba tirẹ̀ jẹ́,
ètè rẹ̀ sì jẹ́ ìdẹ̀kùn fún ọkàn rẹ̀.
 
Ọ̀rọ̀ olófòófó dàbí oúnjẹ àdídùn;
wọ́n a sì wọ ìsàlẹ̀ inú lọ.
 
Ẹni tí kò ṣe déédé nínú iṣẹ́ rẹ̀
arákùnrin ló jẹ́ fún apanirun.
 
10 Orúkọ Olúwa, ilé ìṣọ́ agbára ni;
olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ìgbàlà.
 
11 Ọ̀rọ̀ olówó ni ìlú olódi wọn;
wọ́n rò ó bí i wí pé odi tí kò ṣe é gùn ni.
 
12 Ṣáájú ìṣubú ọkàn ènìyàn a kọ́kọ́ máa gbéraga,
ṣùgbọ́n ìrẹ̀lẹ̀ ni ó máa ń ṣáájú ọlá.
 
13 Ẹni tí ó ń fèsì kí ó tó gbọ́,
èyí ni ìwà òmùgọ̀ àti ìtìjú rẹ̀.
 
14 Ọkàn ènìyàn a máa gbé e ró nígbà àìsàn,
ṣùgbọ́n ta ni ó le forí ti ọkàn tí ó rẹ̀wẹ̀sì.
 
15 Ọkàn olóye ní i gba ìmọ̀;
etí ọlọ́gbọ́n ní í ṣe àwárí rẹ̀.
 
16 Ẹ̀bùn máa ń ṣí ọ̀nà fún ẹni tí ń fún ni lẹ́bùn
a sì mú un wọlé sí ọ̀dọ̀ àwọn olókìkí.
 
17 Ẹni tí ó kọ́kọ́ rọjọ́ máa ń dàbí i pé ó jàre,
títí ẹlòmíràn yóò fi bọ́ síwájú kí ó sì tú àṣírí gbogbo.
 
18 Ìbò dídì máa ń parí ìjà
a sì mú kí àwọn alátakò méjì jìnnà sí ara wọn.
 
19 Arákùnrin tí a ṣẹ̀ sí ṣòro yípadà ju ìlú olódi lọ,
ìjà wọ sì dàbí ọ̀pá ìdábùú ààfin.
 
20 Láti inú èso ẹnu rẹ̀ ikùn ènìyàn a yó;
láti inú ìkórè ẹnu rẹ̀ ni ó ti jẹ yó.
 
21 Ikú àti ìyè ń bẹ nípa ahọ́n wọn,
àwọn tí ó sì fẹ́ràn rẹ̀ yóò jẹ ẹ́.
 
22 Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere,
o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.
 
23 Tálákà ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú,
ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ a dáhùn pẹ̀lú ìkanra.
 
24 Ènìyàn tí ó ní ọ̀rẹ́ púpọ̀ le è parun,
ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ kan wà tí ó súnmọ́ ni tímọ́tímọ́ ju arákùnrin.